Iṣe Apo 4:9-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Bi o ba ṣe pe a nwadi wa loni niti iṣẹ rere ti a ṣe lara abirùn na, bi a ti ṣe mu ọkunrin yi laradá;

10. Ki eyi ki o yé gbogbo nyin ati gbogbo enia Israeli pe, li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, ti Ọlọrun gbé dide kuro ninu okú, nipa rẹ̀ li ọkunrin yi fi duro niwaju nyin ni dida ara ṣaṣa.

11. Eyi li okuta ti a ti ọwọ́ ẹnyin ọmọle kọ̀ silẹ, ti o si di pàtaki igun ile.

12. Kò si si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là.

13. Nigbati nwọn si kiyesi igboiya Peteru on Johanu, ti nwọn si mọ̀ pe, alaikẹkọ ati òpe enia ni nwọn, ẹnu yà wọn; nwọn si woye wọn pe, nwọn a ti ma ba Jesu gbé.

14. Nigbati nwọn si nwò ọkunrin na ti a mu larada, ti o ba wọn duro, nwọn kò ri nkan wi si i.

15. Ṣugbọn nigbati nwọn si paṣẹ pe ki nwọn jade kuro ni igbimọ, nwọn ba ara wọn gbèro,

16. Wipe, Kili a o ti ṣe awọn ọkunrin wọnyi? ti pe iṣẹ àmi ti o daju ti ọwọ́ wọn ṣe, o hàn gbangba fun gbogbo awọn ti ngbé Jerusalemu; awa kò si le sẹ́ ẹ.

Iṣe Apo 4