13. Nigbati nwọn si kiyesi igboiya Peteru on Johanu, ti nwọn si mọ̀ pe, alaikẹkọ ati òpe enia ni nwọn, ẹnu yà wọn; nwọn si woye wọn pe, nwọn a ti ma ba Jesu gbé.
14. Nigbati nwọn si nwò ọkunrin na ti a mu larada, ti o ba wọn duro, nwọn kò ri nkan wi si i.
15. Ṣugbọn nigbati nwọn si paṣẹ pe ki nwọn jade kuro ni igbimọ, nwọn ba ara wọn gbèro,
16. Wipe, Kili a o ti ṣe awọn ọkunrin wọnyi? ti pe iṣẹ àmi ti o daju ti ọwọ́ wọn ṣe, o hàn gbangba fun gbogbo awọn ti ngbé Jerusalemu; awa kò si le sẹ́ ẹ.
17. Ṣugbọn ki o má bà tàn kalẹ siwaju mọ́ lãrin awọn enia, ẹ jẹ ki a kìlọ fun wọn pe, lati isisiyi lọ ki nwọn ki o máṣe fi orukọ yi sọ̀rọ fun ẹnikẹni mọ́.