Iṣe Apo 27:41-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Nigbati nwọn si de ibiti okun meji pade, nwọn fi ori ọkọ̀ sọlẹ; iwaju rẹ̀ si kàn mọlẹ ṣinṣin, o duro, kò le yi, ṣugbọn agbara riru omi bẹrẹ si fọ́ idi ọkọ̀ na.

42. Ero awọn ọmọ-ogun ni ki a pa awọn onde, ki ẹnikẹni wọn ki o má ba wẹ̀ jade sá lọ.

43. Ṣugbọn balogun ọrún nfẹ gbà Paulu là, o kọ̀ ero wọn; o si paṣẹ fun awọn ti o le wẹ̀ ki nwọn ki o kọ́ bọ si okun lọ si ilẹ,

44. Ati awọn iyokù, omiran lori apako, ati omiran lori ẹfọkọ̀. Bẹ̃li o si ṣe ti gbogbo wọn yọ, li alafia de ilẹ.

Iṣe Apo 27