Iṣe Apo 25:14-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Bi nwọn si ti wà nibẹ̀ li ọjọ pipọ, Festu mu ọ̀ran Paulu wá siwaju ọba, wipe, Feliksi fi ọkunrin kan silẹ li ondè:

15. Ẹniti awọn olori alufa ati awọn agbàgba awọn Ju fi sùn nigbati mo wà ni Jerusalemu nwọn nfẹ ki n da a lẹbi.

16. Awọn ẹniti mo si da lohùn pe, Kì iṣe iṣe awọn ara Romu lati da ẹnikẹni lẹbi, ki ẹniti a fisùn ki o to kò awọn olufisùn rẹ̀ loju, ki o si ri àye wi ti ẹnu rẹ̀, nitori ọ̀ran ti a kà si i lọrùn,

17. Nitorina nigbati nwọn jùmọ wá si ihinyi, emi kò jafara, nijọ keji mo joko lori itẹ́ idajọ, mo si paṣẹ pe ki a mu ọkunrin na wá.

18. Nigbati awọn olufisùn na dide, nwọn kò kà ọ̀ran buburu iru eyi ti mo rò si i lọrùn.

19. Ṣugbọn nwọn ni ọ̀ran kan si i, niti isin wọn, ati niti Jesu kan ti o ti kú, ti Paulu tẹnumọ́ pe o wà lãye.

20. Bi emi kò si ti mọ̀ bi a iti wadi nkan wọnyi, mo bi i lere bi o nfẹ lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀.

Iṣe Apo 25