Iṣe Apo 19:18-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ọ̀pọ awọn ti nwọn gbagbọ́ si wá, nwọn jẹwọ, nwọn si fi iṣẹ wọn hàn.

19. Kì isi ṣe diẹ ninu awọn ti nṣe àlúpàyídà li o kó iwe wọn jọ, nwọn dáná sun wọn loju gbogbo enia: nwọn si ṣírò iye wọn, nwọn si ri i, o jẹ ẹgbã-mẹdọgbọ̀n iwọn fadaka.

20. Bẹ̃li ọ̀rọ Oluwa si gbilẹ si i gidigidi, o si gbilẹ.

21. Njẹ bi nkan wọnyi ti pari tan, Paulu pinnu rẹ̀ li ọkàn pe, nigbati on ba kọja ni Makedonia ati Akaia, on ó lọ si Jerusalemu, o wipe, Lẹhin igba ti mo ba de ibẹ̀, emi kò le ṣaima ri Romu pẹlu.

22. Nigbati o si ti rán meji ninu awọn ti nṣe iranṣẹ fun u lọ si Makedonia, Timotiu ati Erastu, on tikararẹ̀ duro ni Asia ni igba diẹ na.

23. Li akokò na èmìmì diẹ ki o wà nitori Ọna na.

24. Nitori ọkunrin kan ti a npè ni Demetriu, alagbẹdẹ fadaka, ti ima fi fadaka ṣe ile-oriṣa fun Diana, o mu ère ti kò mọ̀ ni iwọn fun awọn oniṣọnà wá;

25. Nigbati o pè wọn jọ, ati irú awọn ọlọnà bẹ̃, o ni, Alàgba, ẹnyin mọ̀ pe nipa iṣẹ-ọna yi li awa fi li ọrọ̀ wa.

26. Ẹnyin si ri, ẹ si gbọ́ pe, kì iṣe ni Efesu nikanṣoṣo ni, ṣugbọn o fẹrẹ ṣe gbogbo Asia, ni Paulu yi nyi ọ̀pọ enia li ọkàn pada, ti o si ndari wọn wipe, Ohun ti a fi ọwọ́ ṣe, kì iṣe ọlọrun.

27. Ki si iṣe pe kìki iṣẹ-ọnà wa yi li o wà li ewu ati di asan; ṣugbọn ile Diana oriṣa nla yio si di gigàn pẹlu, ati gbogbo ọla nla rẹ̀ yio si run, ẹniti gbogbo Asia ati gbogbo aiye mbọ.

Iṣe Apo 19