6. Ati awọn aposteli ati awọn àgbagbà pejọ lati gbìmọ ọ̀ran yi.
7. Nigbati iyàn si di pipọ, Peteru dide, o si wi fun wọn pe, Ará, ẹnyin mọ̀ pe, lati ibẹrẹ Ọlọrun ti yàn ninu nyin, ki awọn Keferi ki o le gbọ́ ọ̀rọ ihinrere li ẹnu mi, ki nwọn si gbagbọ́.
8. Ati Ọlọrun, ti iṣe olumọ-ọkàn, o jẹ wọn li ẹrí, o nfun wọn li Ẹmí Mimọ́, gẹgẹ bi awa:
9. Kò si fi iyatọ si ãrin awa ati awọn, o nfi igbagbọ́ wẹ̀ wọn li ọkàn mọ́.
10. Njẹ nitorina ẽṣe ti ẹnyin o fi dán Ọlọrun wò, lati fi àjaga bọ̀ awọn ọmọ-ẹhin li ọrùn, eyiti awọn baba wa ati awa kò le rù?
11. Ṣugbọn awa gbagbọ́ pe nipa ore-ọfẹ Oluwa Jesu awa ó là, gẹgẹ bi awọn.
12. Gbogbo ajọ si dakẹ, nwọn si fi eti si Barnaba on Paulu, ti nwọn nròhin iṣẹ aṣẹ ati iṣẹ àmi ti Ọlọrun ti ti ọwọ́ wọn ṣe lãrin awọn Keferi.
13. Lẹhin ti nwọn si dakẹ, Jakọbu dahùn, wipe, Ará, ẹ gbọ ti emi:
14. Simeoni ti rohin bi Ọlọrun li akọṣe ti bojuwò awọn Keferi, lati yàn enia ninu wọn fun orukọ rẹ̀.
15. Ati eyiyi li ọ̀rọ awọn woli ba ṣe dede; bi a ti kọwe rẹ̀ pe,
16. Lẹhin nkan wọnyi li emi o pada, emi o si tún agọ́ Dafidi pa ti o ti wó lulẹ; emi ó si tún ahoro rẹ̀ kọ́, emi ó si gbé e ró:
17. Ki awọn enia iyokù le mã wá Oluwa, ati gbogbo awọn Keferi lara ẹniti a npè orukọ mi,
18. Li Oluwa wi, ẹniti o sọ gbogbo nkan wọnyi di mimọ̀ fun Ọlọrun ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo, lati igba ọjọ ìwa.