Nigbati iyàn si di pipọ, Peteru dide, o si wi fun wọn pe, Ará, ẹnyin mọ̀ pe, lati ibẹrẹ Ọlọrun ti yàn ninu nyin, ki awọn Keferi ki o le gbọ́ ọ̀rọ ihinrere li ẹnu mi, ki nwọn si gbagbọ́.