23. Nigbati nwọn si ti yàn awọn àgbagba fun olukuluku ijọ, ti nwọn si ti fi àwẹ gbadura, nwọn fi wọn le Oluwa lọwọ, ẹniti nwọn gbagbọ́.
24. Nigbati nwọn si là Pisidia já, nwọn wá si Pamfilia.
25. Nigbati nwọn si ti sọ ọ̀rọ na ni Perga, nwọn sọkalẹ lọ si Atalia:
26. Ati lati ibẹ̀ lọ nwọn ba ti ọkọ̀ lọ si Antioku, lati ibiti a gbé ti fi wọn le õre-ọfẹ Ọlọrun lọwọ, fun iṣẹ ti nwọn ṣe pari.