Iṣe Apo 10:8-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nigbati o si ti rohin ohun gbogbo fun wọn, o rán wọn lọ si Joppa.

9. Ni ijọ keji bi nwọn ti nlọ li ọ̀na àjo wọn, ti nwọn si sunmọ ilu na, Peteru gùn oke ile lọ igbadura niwọn wakati kẹfa ọjọ:

10. Ebi si pa a gidigidi, on iba si jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn npèse, o bọ si ojuran,

11. O si ri ọrun ṣí, ohun elo kan si sọkalẹ bi gọgọwú nla, ti a ti igun mẹrẹrin, sọkalẹ si ilẹ.

12. Ninu rẹ̀ li olorijorí ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin wà, ati ohun ti nrakò li aiye ati ẹiyẹ oju ọrun.

13. Ohùn kan si fọ̀ si i pe, Dide, Peteru; mã pa ki o si mã jẹ.

14. Ṣugbọn Peteru dahùn pe, Agbẹdọ, Oluwa; nitori emi kò jẹ ohun èwọ ati alaimọ́ kan ri.

15. Ohùn kan si tún fọ̀ si i lẹkeji pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ mọ́.

Iṣe Apo 10