14. Nitori, ará, ẹnyin di alafarawe awọn ijọ Ọlọrun ti mbẹ ni Judea, ninu Kristi Jesu: nitoripe ẹnyin pẹlu jìya iru ohun kanna lọwọ awọn ara ilu nyin, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti jìya lọwọ awọn Ju:
15. Awọn ẹniti o pa Jesu Oluwa, ati awọn woli, nwọn si tì wa jade; nwọn kò si ṣe eyiti o wu Ọlọrun, nwọn si wà lodi si gbogbo enia:
16. Nwọn kọ̀ fun wa lati sọ̀rọ fun awọn Keferi ki nwọn ki o le là, lati mã sọ ẹ̀ṣẹ wọn di kikun nigbagbogbo: ṣugbọn ibinu de bá wọn titi de opin.
17. Ṣugbọn, ará, awa ti a gbà kuro lọdọ nyin fun sã kan li ara, ki iṣe li ọkàn, pẹlu itara ọpọlọpọ li awa ṣe aniyan ti a si fẹ gidigidi lati ri oju nyin.
18. Nitori awa fẹ lati tọ̀ nyin wá, ani emi Paulu lẹ̃kini ati lẹ̃keji; Satani si dè wa li ọ̀na.
19. Nitori kini ireti wa, tabi ayọ̀ wa, tabi ade iṣogo wa? kì ha iṣe ẹnyin ni niwaju Jesu Oluwa wa ni àbọ rẹ̀?