5. Ṣugbọn iba wu mi ki gbogbo nyin le mã sọ oniruru ède, ṣugbọn ki ẹ kuku mã sọtẹlẹ: nitori ẹniti nsọtẹlẹ pọ̀ju ẹniti nsọ oniruru ède lọ, ayaṣebi o ba nṣe itumọ̀, ki ijọ ki o le kọ́ ẹkọ́.
6. Njẹ nisisiyi, ará, bi mo ba wá si arin nyin, ti mo si nsọrọ li ede aimọ̀, ère kili emi o jẹ fun nyin, bikoṣepe mo ba mba nyin sọrọ, yala nipa iṣipaya, tabi nipa imọ̀, tabi nipa isọtẹlẹ, tabi nipa ẹkọ́?
7. Bẹni pẹlu awọn nkan ti kò li ẹmí ti ndún, ibã ṣe fère tabi dùru, bikoṣepe ìyatọ ba wà ninu ohùn wọn, a ó ti ṣe mọ̀ ohun ti fère tabi ti dùru nwi?
8. Nitoripe bi ohùn ipè kò ba daju, tani yio mura fun ogun?
9. Bẹ̃ si li ẹnyin, bikoṣepe ẹnyin ba nfi ahọ́n nyin sọrọ ti o ye ni, a o ti ṣe mọ̀ ohun ti a nwi? nitoripe ẹnyin o sọ̀rọ si ofurufu.
10. O le jẹ pe oniruru ohùn ni mbẹ li aiye, kò si si ọ̀kan ti kò ni itumọ.
11. Njẹ bi emi kò mọ̀ itumọ ohùn na, emi o jasi alaigbede si ẹniti nsọ̀rọ, ẹniti nsọ̀rọ yio si jasi alaigbede si mi.
12. Bẹ̃ si li ẹnyin, bi ẹnyin ti ni itara fun ẹ̀bun ẹmí, ẹ mã ṣe afẹri ati mã pọ si i fun idàgbàsoke ijọ.
13. Nitorina jẹ ki ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ gbadura ki o le mã ṣe itumọ̀.
14. Nitori bi emi ba ngbadura li ède aimọ̀, ẹmí mi ngbadura, ṣugbọn oye mi jẹ alaileso.
15. Njẹ kini rè? Emi o fi ẹmí gbadura, emi o si fi oye gbadura pẹlu: emi o fi ẹmí kọrin, emi o si fi oye kọrin pẹlu.
16. Bi bẹ̃kọ, bi iwọ ba súre nipa, ẹmí, bawo ni ẹniti mbẹ ni ipò òpe yio ṣe ṣe Amin si idupẹ rẹ, nigbati kò mọ ohun ti iwọ wi?
17. Nitori iwọ dupẹ gidigidi nitõtọ, ṣugbọn a kò fi ẹsẹ ẹnikeji rẹ mulẹ.
18. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun ti emi nfọ oniruru ede jù gbogbo nyin lọ:
19. Ṣugbọn mo fẹ ki ng kuku fi oye mi sọ ọ̀rọ marun ni ijọ, ki ng le kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu, jù ẹgbãrun ọ̀rọ li ède aimọ̀.
20. Ará, ẹ máṣe jẹ ọmọde ni oye: ṣugbọn ẹ jẹ ọmọde li arankan, ṣugbọn ni oye ki ẹ jẹ agba.
21. A ti kọ ọ ninu ofin pe, Nipa awọn alahọn miran ati elete miran li emi ó fi bá awọn enia yi sọrọ; sibẹ nwọn kì yio gbọ temi, li Oluwa wi.
22. Nitorina awọn ahọn jasi àmi kan, kì iṣe fun awọn ti o gbagbọ́, bikoṣe fun awọn alaigbagbọ́: ṣugbọn isọtẹlẹ kì iṣe fun awọn ti kò gbagbọ́, bikoṣe fun awọn ti o gbagbọ́.
23. Njẹ bi gbogbo ijọ ba pejọ si ibi kan, ti gbogbo nwọn si nfi ède fọ̀, bi awọn ti iṣe alailẹkọ́ ati alaigbagbọ́ ba wọle wá, nwọn kì yio ha wipe ẹnyin nṣe wère?
24. Ṣugbọn bi gbogbo nyin ba nsọtẹlẹ, ti ẹnikan ti kò gbagbọ́ tabi ti kò li ẹ̀kọ́ bá wọle wá, gbogbo nyin ni yio fi òye ẹ̀ṣẹ yé e, gbogbo nyin ni yio wadi rẹ̀: