21. Oju kò si le wi fun ọwọ́ pe, emi kò ni ifi ọ ṣe: tabi ki ori wi ẹ̀wẹ fun ẹsẹ pe, emi kò ni ifi nyin ṣe.
22. Ṣugbọn awọn ẹ̀ya ara wọnni ti o dabi ẹnipe nwọn ṣe ailera jù, awọn li a kò le ṣe alaini jù:
23. Ati awọn ẹ̀ya ara wọnni ti awa rò pe nwọn ṣe ailọlá jù, lori wọnyi li awa si nfi ọlá si jù; bẹni ibi aiyẹ wa si ni ẹyẹ lọpọlọpọ jù.
24. Nitoripe awọn ibi ti o li ẹyẹ li ara wa kò fẹ ohun kan: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe ara lọkan, o si fi ọ̀pọlọpọ ọlá fun ibi ti o ṣe alaini:
25. Ki ìyapa ki o máṣe si ninu ara; ṣugbọn ki awọn ẹ̀ya ara ki o le mã ṣe aniyan kanna fun ara wọn.
26. Bi ẹ̀ya kan ba si njìya, gbogbo ẹ̀ya a si jùmọ ba a jìya; tabi bi a ba mbọla fun ẹ̀ya kan, gbogbo ẹ̀ya a jùmọ ba a yọ̀.