1. A. Ọba 6:26-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Giga kerubu kan jẹ igbọnwọ mẹwa, bẹ̃ni ti kerubu keji.

27. O si fi awọn kerubu sinu ile ti inu lọhun, nwọn si nà iyẹ-apa kerubu na, tobẹ̃ ti iyẹ-apa ọkan si kàn ogiri kan, ati iyẹ-apa kerubu keji si kàn ogiri keji: iyẹ-apa wọn si kàn ara wọn larin ile na.

28. O si fi wura bò awọn kerubu na.

29. O si yá aworan awọn kerubu lara gbogbo ogiri ile na yikakiri ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko, ninu ati lode.

1. A. Ọba 6