13. Emi o si ma gbe ãrin awọn ọmọ Israeli, emi kì o si kọ̀ Israeli, enia mi.
14. Solomoni si kọ́ ile na, o si pari rẹ̀.
15. O si fi apako kedari tẹ́ ogiri ile na ninu, lati ilẹ ile na de àja rẹ̀; o fi igi bò wọn ninu, o si fi apako firi tẹ́ ilẹ ile na.
16. O si kọ́ ogún igbọnwọ ni ikangun ile na, lati ilẹ de àja ile na li o fi apako kedari kọ́, o tilẹ kọ́ eyi fun u ninu, fun ibi-idahùn, ani ibi-mimọ́-julọ.
17. Ati ile na, eyini ni Tempili niwaju rẹ̀, jẹ ogoji igbọnwọ ni gigùn.
18. Ati kedari ile na ninu ile li a fi irudi ati itanna ṣe iṣẹ ọnà rẹ̀: gbogbo rẹ̀ kiki igi kedari; a kò ri okuta kan.
19. Ibi-mimọ́-julọ na li o mura silẹ ninu ile lati gbe apoti majẹmu Oluwa kà ibẹ.
20. Ibi-mimọ́-julọ na si jasi ogún igbọnwọ ni gigùn, li apa ti iwaju, ati ogún igbọnwọ ni ibú, ati ogún igbọnwọ ni giga rẹ̀; o si fi wura ailadàlu bò o, bẹ̃li o si fi igi kedari bò pẹpẹ.