11. Natani si wi fun Batṣeba, iya Solomoni pe, Iwọ kò gbọ́ pe, Adonijah, omọ Haggiti jọba, Dafidi, oluwa wa, kò si mọ̀?
12. Nitorina, wá nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, emi o si fun ọ ni ìmọ, ki iwọ ki o le gbà ẹmi rẹ là, ati ẹmi Solomoni ọmọ rẹ.
13. Lọ, ki o si tọ̀ Dafidi, ọba lọ, ki o si wi fun u pe, Ọba, oluwa mi, ṣe iwọ li o bura fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, pe, nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, ni yio jọba lẹhin mi, on ni o si joko lori itẹ mi? ẽṣe ti Adonijah fi jọba?
14. Kiyesi i, bi iwọ ti mba ọba sọ̀rọ lọwọ, emi o si tẹle ọ, emi o si wá ikún ọ̀rọ rẹ.
15. Batṣeba si tọ̀ ọba lọ ni iyẹ̀wu: ọba si gbó gidigidi: Abiṣagi, ara Ṣunemu, si nṣe iranṣẹ fun ọba.
16. Batṣeba si tẹriba, o si wolẹ fun ọba. Ọba si wipe, Kini iwọ nfẹ?
17. On si wi fun u pe, oluwa mi, iwọ fi Oluwa Ọlọrun rẹ bura fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin pe, nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, yio jọba lẹhin mi, on o si joko lori itẹ mi.
18. Sa wò o, nisisiyi, Adonijah jọba; iwọ, oluwa mi ọba, kò si mọ̀.
19. O si pa malu ati ẹran ti o li ọra, ati agùtan li ọ̀pọlọpọ, o si pe gbogbo awọn ọmọ ọba, ati Abiatari alufa, ati Joabu balogun: ṣugbọn Solomoni iranṣẹ rẹ ni kò pè.
20. Ati iwọ, oluwa mi, ọba, oju gbogbo Israeli mbẹ lara rẹ, ki iwọ ki o sọ fun wọn, tani yio joko lori itẹ oluwa mi ọba lẹhin rẹ̀?
21. Yio si ṣe, nigbati oluwa mi ọba ba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a o si kà emi ati Solomoni ọmọ mi si ẹlẹṣẹ̀.
22. Si wò o, bi o si ti mba ọba sọ̀rọ lọwọ, Natani woli si wọle.
23. Nwọn si sọ fun ọba pe, Wò o, Natani woli. Nigbati o si wá siwaju ọba, o wolẹ̀, o si dojubolẹ.
24. Natani si wipe, oluwa mi, ọba! iwọ ha wipe, Adonijah ni yio jọba lẹhin mi ati pe, on o si joko lori itẹ mi bi?
25. Nitori o sọkalẹ lọ loni, o si pa malu ati ẹran ọlọra, ati agùtan li ọ̀pọ-lọpọ, o si pè gbogbo awọn ọmọ ọba, ati awọn balogun, ati Abiatari alufa; si wò o, nwọn njẹ, nwọn si nmu niwaju rẹ̀, nwọn si nwipe, Ki Adonijah ọba ki o pẹ.
26. Ṣugbọn emi, emi iranṣẹ rẹ, ati Sadoku alufa, ati Benaiah ọmọ Jehoiada, ati Solomoni, iranṣẹ rẹ, ni kò pè.
27. Nkan yi ti ọdọ oluwa mi ọba wá bi? iwọ kò si fi ẹniti yio joko lori itẹ oluwa mi ọba lẹhin rẹ̀ hàn iranṣẹ rẹ?