9. Ati emi, kiye si i, emi ba nyin dá majẹmu mi, ati awọn irú-ọmọ nyin lẹhin nyin;
10. Ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin; ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ẹranko aiye pélu nyin; lati gbogbo awọn ti o ti inu ọkọ̀ jade, titi o fi de gbogbo ẹranko aiye.
11. Emi o si ba nyin dá majẹmu mi; a ki yio si fi kíkun-omi ké gbogbo ẹdá kuro mọ́; bẹ̃ni kíkun-omi ki yio sí mọ́, lati pa aiye run.
12. Ọlọrun si wipe, Eyiyi li àmi majẹmu mi ti mo ba nyin dá, ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin, fun atirandiran:
13. Mo fi òṣumare mi si awọsanma, on ni yio si ma ṣe àmi majẹmu mi ti mo ba aiye dá.
14. Yio si ṣe, nigbati mo ba mu awọsanma wá si ori ilẹ, a o si ma ri òṣumare na li awọsanma:
15. Emi o si ranti majẹmu mi, ti o wà lãrin emi ati ẹnyin, ati gbogbo ọkàn alãye ni gbogbo ẹdá; omi ki yio si di kíkun mọ́ lati pa gbogbo ẹdá run.
16. Òṣumare na yio si wà li awọsanma; emi o si ma wò o, ki emi le ma ranti majẹmu lailai ti o wà pẹlu Ọlọrun ati gbogbo ọkàn alãye ti o wà ninu gbogbo ẹdá ti o wà li aiye.
17. Ọlọrun si wi fun Noa pe, Eyiyi li àmi majẹmu na, ti mo ba ara mi ati ẹdá gbogbo ti o wà lori ilẹ dá.
18. Awọn ọmọ Noa, ti o si jade ninu ọkọ̀ ni Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti: Hamu si ni baba Kenaani.
19. Awọn mẹta wọnyi li ọmọ Noa: lati ọdọ wọn li a gbé ti tàn ká gbogbo aiye.