Gẹn 49:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JAKOBU si pè awọn ọmọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ kó ara nyin jọ, ki emi ki o le wi ohun ti yio bá nyin lẹhin-ọla fun nyin.

2. Ẹ kó ara nyin jọ, ki ẹ si gbọ́, ẹnyin ọmọ Jakobu; ki ẹ si fetisi ti Israeli baba nyin.

3. Reubeni, iwọ li akọ́bi mi, agbara mi, ati ipilẹṣẹ ipá mi, titayọ ọlá, ati titayọ agbara.

4. Ẹnirirú bi omi, iwọ ki yio le tayọ; nitori ti iwọ gùn ori ẹni baba rẹ; iwọ si bà a jẹ́: o gùn ori akete mi.

5. Simeoni on Lefi, arakunrin ni nwọn; ohun-èlo ìka ni idà wọn.

6. Ọkàn mi, iwọ máṣe wọ̀ ìmọ wọn; ninu ajọ wọn, ọlá mi, máṣe bá wọn dàpọ; nitoripe, ni ibinu wọn nwọn pa ọkunrin kan, ati ni girimakayi wọn, nwọn já malu ni patì.

7. Ifibú ni ibinu wọn, nitori ti o rorò; ati ikannu wọn, nitori ti o ní ìka: emi o pin wọn ni Jakobu, emi o si tú wọn ká ni Israeli.

8. Judah, iwọ li ẹniti awọn arakunrin rẹ yio ma yìn; ọwọ́ rẹ yio wà li ọrùn awọn ọtá rẹ; awọn ọmọ baba rẹ yio foribalẹ niwaju rẹ.

9. Ọmọ kiniun ni Judah; ọmọ mi, ni ibi-ọdẹ ni iwọ ti goke: o bẹ̀rẹ, o ba bi kiniun, ati bi ogbó kiniun; tani yio lé e dide?

Gẹn 49