Gẹn 46:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Emi o si bá ọ sọkalẹ lọ si Egipti; emi o si mú ọ goke wá nitõtọ: Josefu ni yio si fi ọwọ́ rẹ̀ pa ọ li oju dé.

5. Jakobu si dide lati Beer-ṣeba lọ: awọn ọmọ Israeli si mú Jakobu baba wọn lọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wọn, ati awọn aya wọn, ninu kẹkẹ́-ẹrù ti Farao rán lati mú u lọ.

6. Nwọn si mú ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ti nwọn ní ni ilẹ Kenaani, nwọn si wá si Egipti, Jakobu, ati gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀:

7. Awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin awọn ọmọ rẹ̀, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ li o mú pẹlu rẹ̀ wá si ilẹ Egipti.

8. Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti, Jakobu ati awọn ọmọ rẹ̀: Reubeni, akọ́bi Jakobu.

9. Ati awọn ọmọ Reubeni; Hanoku, ati Pallu, ati Hesroni, ati Karmi.

10. Ati awọn ọmọ Simeoni; Jemueli, ati Jamini, ati Ohadi, ati Jakini, ati Sohari, ati Ṣaulu, ọmọ obinrin ara Kenaani kan.

11. Ati awọn ọmọ Lefi; Gerṣoni, Kohati, ati Merari.

12. Ati awọn ọmọ Judah; Eri ati Onani, ati Ṣela, ati Peresi, ati Sera: ṣugbọn Eri on Onani ti kú ni ilẹ Kenaani. Ati awọn ọmọ Peresi ni Hesroni on Hamulu.

Gẹn 46