6. Lati ọdún meji yi ni ìyan ti nmú ni ilẹ: o si tun kù ọdún marun si i, ninu eyiti a ki yio ni itulẹ tabi ikorè.
7. Ọlọrun si rán mi siwaju nyin lati da irú-ọmọ si fun nyin lori ilẹ, ati lati fi ìgbala nla gbà ẹmi nyin là.
8. Njẹ nisisiyi, ki iṣe ẹnyin li o rán mi si ihin, bikoṣe Ọlọrun: o si ti fi mi ṣe baba fun Farao, ati oluwa gbogbo ile rẹ̀, ati alakoso gbogbo ilẹ Egipti.
9. Ẹ yara ki ẹ si goke tọ̀ baba mi lọ, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi ni Josefu ọmọ rẹ wipe, Ọlọrun fi mi jẹ́ oluwa gbogbo Egipti: sọkalẹ tọ̀ mi wá, má si ṣe duro.
10. Iwọ o si joko ni ilẹ Goṣeni, iwọ o si wà leti ọdọ mi, iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ, ati ọwọ-ẹran rẹ, ati ọwọ́-malu rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní.
11. Nibẹ̀ li emi o si ma bọ́ ọ; nitori ọdún ìyan kù marun si i; ki iwọ, ati awọn ara ile rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní, ki o má ba ri ipọnju.
12. Si kiyesi i, oju nyin, ati oju Benjamini arakunrin mi ri pe, ẹnu mi li o nsọ̀rọ fun nyin.
13. Ki ẹnyin ki o si ròhin gbogbo ogo mi ni Egipti fun baba mi, ati ti ohun gbogbo ti ẹnyin ri; ki ẹnyin ki o si yara, ki ẹ si mú baba mi sọkalẹ wá ihin.
14. O si rọ̀mọ́ Benjamini arakunrin rẹ̀ li ọrùn, o si sọkun; Benjamini si sọkun li ọrùn rẹ̀.
15. O si fi ẹnu kò gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li ẹnu, o si sọkun si wọn lara: lẹhin eyini li awọn arakunrin rẹ̀ bá a sọ̀rọ.
16. A si gbọ́ ìhin na ni ile Farao pe, awọn arakunrin Josefu dé: o si dùn mọ́ Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀.
17. Farao si wi fun Josefu pe, Wi fun awọn arakunrin rẹ, Eyi ni ki ẹ ṣe; ẹ dì ẹrù lé ẹranko nyin, ki ẹ si lọ si ilẹ Kenaani;