23. O si wi fun wọn pe, Alafia ni fun nyin, ẹ má bẹ̀ru: Ọlọrun nyin ati Ọlọrun baba nyin, li o fun nyin ni iṣura ninu àpo nyin: owo nyin dé ọwọ́ mi. O si mú Simeoni jade tọ̀ wọn wá.
24. Ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na wá si ile Josefu, o si fun wọn li omi, nwọn si wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn; o si fun awọn kẹtẹkẹtẹ wọn li ohun jijẹ.
25. Nwọn si ti mú ọrẹ na silẹ dè atibọ̀ Josefu lọsán: nitori ti nwọn gbọ́ pe nwọn o jẹun nibẹ̀.
26. Nigbati Josefu si wọlé, nwọn si mú ọrẹ ti o wà li ọwọ́ wọn fun u wá sinu ile, nwọn si tẹriba fun u ni ilẹ.
27. On si bère alafia wọn, o si wipe, Alafia ki baba nyin wà, arugbo na ti ẹnyin wi? o wà lãye sibẹ̀?
28. Nwọn si dahun pe, Ara baba wa, iranṣẹ rẹ le, o wà sibẹ̀. Nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si bù ọlá fun u.
29. O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri Benjamini, aburo rẹ̀, ọmọ iya rẹ̀, o si wipe, Abikẹhin nyin na ti ẹnyin wi fun mi li eyi? o si wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe ojurere si ọ, ọmọ mi.
30. Josefu si yara; nitori ti inu yọ́ ọ si aburo rẹ̀: o wá ibi ti yio gbé sọkun; o si bọ́ si iyẹwu, o si sọkun nibẹ̀.
31. O si bọju rẹ̀, o si jade; o si mú oju dá, o si wipe, Ẹ gbé onjẹ kalẹ.
32. Nwọn si gbé tirẹ̀ kalẹ fun u lọ̀tọ, ati fun wọn lọ̀tọ, ati fun awọn ara Egipti ti o mbá a jẹun lọ̀tọ; nitori ti awọn ara Egipti kò gbọdọ bá awọn enia Heberu jẹun; nitori irira ni fun awọn ara Egipti.
33. Nwọn si joko niwaju rẹ̀, akọ́bi gẹgẹ bi ipò ibí rẹ̀, ati abikẹhin gẹgẹ bi ipò ewe rẹ̀: ẹnu si yà awọn ọkunrin na si ara wọn.
34. O si bù onjẹ fun wọn lati iwaju rẹ̀ lọ: ṣugbọn onjẹ Benjamini jù ti ẹnikẹni wọn lẹrinmarun. Nwọn si mu, nwọn si bá a ṣe ariya.