1. ÌYAN na si mú ni ilẹ na gidigidi.
2. O si ṣe, nigbati nwọn jẹ ọkà ti nwọn ti múbọ̀ Egipti wá tán, baba wọn wi fun wọn pe, Ẹ tun lọ irà onjẹ diẹ fun wa wá.
3. Judah si wi fun u pe, ọkunrin na tẹnumọ́ ọ gidigidi fun wa pe, Ẹnyin kò gbọdọ ri oju mi, bikoṣepe arakunrin nyin ba pẹlu nyin.
4. Bi iwọ o ba rán arakunrin wa pẹlu wa, awa o sọkalẹ lọ lati rà onjẹ fun ọ:
5. Ṣugbọn bi iwọ ki yio ba rán a, awa ki yio sọkalẹ lọ: nitoriti ọkunrin na wi fun wa pe, Ẹnyin ki yio ri oju mi, bikoṣe arakunrin nyin ba pẹlu nyin.
6. Israeli si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi hùwa buburu bẹ̃ si mi, ti ẹnyin fi wi fun ọkunrin na pe, ẹnyin ní arakunrin kan pẹlu?
7. Nwọn si wipe, ọkunrin na bère timọtimọ niti awa tikara wa, ati niti ibatan wa, wipe, Baba nyin wà sibẹ̀? ẹnyin li arakunrin miran? awa si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi: awa o ti ṣe le mọ̀ daju pe yio wipe, Mú arakunrin nyin sọkalẹ wá?
8. Judah si wi fun Israeli baba rẹ̀ pe, Rán ọdọmọde na ba mi lọ, awa o si dide, a o lọ; ki awa ki o le yè, ki a má si ṣe kú, ati awa ati iwọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wa.
9. Emi ni yio ṣe onigbọwọ rẹ̀: li ọwọ́ mi ni iwọ o bère rẹ̀; bi emi kò ba mú u pada fun ọ wá, ki nsi mu u duro niwaju rẹ, njẹ emi ni yio rù ẹbi na lailai.
10. Bikoṣepe bi awa ti nṣe ilọra, awa iba sa ti pada bọ̀ lẹrinkeji nisisiyi.
11. Israeli baba wọn si wi fun wọn pe, Njẹ bi bẹ̃ ba ni, eyi ni ki ẹ ṣe, ẹ mú ninu ãyo eso ilẹ yi, sinu ohun-èlo nyin, ki ẹ si mú ọrẹ lọ fun ọkunrin na, ikunra diẹ, ati oyin diẹ, ati turari, ojia, eso pupa, ati eso almondi:
12. Ki ẹ si mú owo miran li ọwọ́ nyin; ati owo ti a mú pada wá li ẹnu àpo nyin, ẹ si tun mú u li ọwọ́ lọ; bọya o le ṣe èṣi:
13. Ẹ mú arakunrin nyin pẹlu, ẹ si dide, ẹ tun pada tọ̀ ọkunrin na lọ:
14. Ki Ọlọrun Olodumare ki o si fun nyin li ãnu niwaju ọkunrin na, ki o le rán arakunrin nyin ọhún wá, ati Benjamini. Bi a ba gbà mi li ọmọ, a gbà mi li ọmọ.
15. Awọn ọkunrin na si mú ọrẹ na, nwọn si mú iṣẹ́po owo meji li ọwọ́ wọn, ati Benjamini; nwọn si dide, nwọn si sọkalẹ lọ si Egipti, nwọn si duro niwaju Josefu.
16. Nigbati Josefu si ri Benjamini pẹlu wọn, o wi fun olori ile rẹ̀ pe, Mú awọn ọkunrin wọnyi rè ile, ki o si pa ẹran, ki o si pèse: nitori ti awọn ọkunrin wọnyi yio ba mi jẹun li ọjọkanri.
17. Ọkunrin na si ṣe bi Josefu ti wi; ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na lọ si ile Josefu.
18. Awọn ọkunrin na si mbẹ̀ru, nitori ti a mú wọn wá si ile Josefu; nwọn si wipe, Nitori owo ti a mú pada sinu àpo wa li akọ́wa li a ṣe mú wa wọle; ki o le fẹ wa lẹfẹ, ki o si le kọlù wa, ki o si le kó wa ṣe ẹrú ati awọn kẹtẹkẹtẹ wa.