Nwọn si wipe, ọkunrin na bère timọtimọ niti awa tikara wa, ati niti ibatan wa, wipe, Baba nyin wà sibẹ̀? ẹnyin li arakunrin miran? awa si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi: awa o ti ṣe le mọ̀ daju pe yio wipe, Mú arakunrin nyin sọkalẹ wá?