Gẹn 36:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli; Nahati, ati Sera, Ṣamma, ati Misa: awọn wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau.

14. Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, aya Esau: on si bí Jeuṣi fun Esau, ati Jaalamu, ati Kora.

15. Awọn wọnyi ni olori ninu awọn ọmọ Esau: awọn ọmọ Elifasi, akọ́bi Esau; Temani olori, Omari olori, Sefo olori, Kenasi olori,

16. Kora olori, Gatamu olori, Amaleki olori: wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Elifasi wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Ada.

17. Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli ọmọ Esau; Nahati olori, Sera olori, Ṣamma olori, Misa olori; wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Reueli wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau.

18. Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, aya Esau; Jeuṣi olori, Jaalamu olori, Kora olori: wọnyi li awọn ti o ti ọdọ Aholibama wá, aya Esau, ọmọbinrin Ana.

19. Wọnyi li awọn ọmọ Esau, eyini ni Edomu, wọnyi si li awọn olori wọn.

20. Wọnyi li awọn ọmọ Seiri, enia Hori, ti o tẹ̀dó ni ilẹ na; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana,

21. Ati Diṣoni, ati Eseri, ati Diṣani: wọnyi li awọn olori enia Hori, awọn ọmọ Seiri ni ilẹ Edomu.

22. Ati awọn ọmọ Lotani ni Hori ati Hemamu: arabinrin Lotani si ni Timna.

23. Ati awọn ọmọ Ṣobali ni wọnyi; Alfani, ati Mahanati, ati Ebali, Sefo, ati Onamu.

Gẹn 36