Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, aya Esau; Jeuṣi olori, Jaalamu olori, Kora olori: wọnyi li awọn ti o ti ọdọ Aholibama wá, aya Esau, ọmọbinrin Ana.