Gẹn 33:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JAKOBU si gbé oju rẹ̀ soke, o si wò, si kiyesi i, Esau dé, ati irinwo ọkunrin pẹlu rẹ̀. On si pín awọn ọmọ fun Lea, ati fun Rakeli, ati fun awọn iranṣẹbinrin mejeji.

2. O si tì awọn iranṣẹbinrin ati awọn ọmọ wọn ṣaju, ati Lea ati awọn ọmọ rẹ̀ tẹle wọn, ati Rakeli ati Josefu kẹhin.

3. On si kọja lọ siwaju wọn, o si wolẹ li ẹrinmeje titi o fi dé ọdọ arakunrin rẹ̀.

4. Esau si sure lati pade rẹ̀, o si gbá a mú, o si rọmọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: nwọn si sọkun.

5. O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri awọn obinrin ati awọn ọmọ; o si bi i pe, Tani wọnyi pẹlu rẹ? On si wipe, Awọn ọmọ ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ fun iranṣẹ rẹ ni.

6. Nigbana li awọn iranṣẹbinrin sunmọ ọdọ rẹ̀, awọn ati awọn ọmọ wọn, nwọn si tẹriba.

7. Ati Lea pẹlu ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba: nikẹhin ni Josefu ati Rakeli si sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba.

8. O si wipe, Kini iwọ fi ọwọ́ ti mo pade ni pè? On si wipe, Lati fi ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi ni.

9. Esau si wipe, Emi ní tó, arakunrin mi; pa eyiti o ní mọ́ fun ara rẹ.

10. Jakobu si wipe, Bẹ̃kọ, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi, njẹ gbà ọrẹ mi lọwọ mi: nitori ti emi sa ri oju rẹ bi ẹnipe emi ri oju Ọlọrun, ti inu rẹ si dùn si mi;

Gẹn 33