1. JAKOBU si nlọ li ọ̀na rẹ̀, awọn angeli Ọlọrun si pade rẹ̀.
2. Nigbati Jakobu si ri wọn, o ni, Ogun Ọlọrun li eyi: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Mahanaimu.
3. Jakobu si ranṣẹ siwaju rẹ̀ si Esau, arakunrin rẹ̀, si ilẹ Seiri, pápa oko Edomu.
4. O si rán wọn wipe, Bayi ni ki ẹnyin ki o wi fun Esau, oluwa mi; Bayi ni Jakobu iranṣẹ rẹ wi, Mo ti ṣe atipo lọdọ Labani, mo si ti ngbé ibẹ̀ titi o fi di isisiyi:
5. Mo si ní malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agbo-ẹran, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin: mo si ranṣẹ wá wi fun oluwa mi, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ.
6. Awọn onṣẹ si pada tọ̀ Jakobu wá, wipe, Awa dé ọdọ Esau, arakunrin rẹ, o si mbọ̀wá kò ọ, irinwo ọkunrin li o si wà pẹlu rẹ̀.
7. Nigbana li ẹ̀ru bà Jakobu gidigidi, ãjo si mú u, o si pín awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, ati awọn ọwọ́-ẹran, awọn ọwọ́-malu, ati awọn ibakasiẹ, si ipa meji;
8. O si wipe, bi Esau ba kàn ẹgbẹ kan, ti o si kọlù u, njẹ ẹgbẹ keji ti o kù yio là.