Awọn onṣẹ si pada tọ̀ Jakobu wá, wipe, Awa dé ọdọ Esau, arakunrin rẹ, o si mbọ̀wá kò ọ, irinwo ọkunrin li o si wà pẹlu rẹ̀.