Gẹn 3:20-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Adamu si pè orukọ aya rẹ̀ ni Efa; nitori on ni iṣe iya alãye gbogbo.

21. Ati fun Adamu ati fun aya rẹ̀ li OLUWA Ọlọrun da ẹwu awọ, o si fi wọ̀ wọn.

22. OLUWA Ọlọrun si wipe, Wò o, ọkunrin na dabi ọkan ninu wa lati mọ̀ rere ati bururu: njẹ nisisiyi ki o má ba nà ọwọ́ rẹ̀ ki o si mu ninu eso igi ìye pẹlu, ki o si jẹ, ki o si yè titi lai;

23. Nitorina OLUWA Ọlọrun lé e jade kuro ninu ọgbà Edeni, lati ma ro ilẹ ninu eyiti a ti mu u jade wá.

24. Bẹ̃li o lé ọkunrin na jade; o si fi awọn kerubu ati idà ina dè ìha ìla-õrùn Edeni ti njù kakiri, lati ma ṣọ́ ọ̀na igi ìye na.

Gẹn 3