51. Wò o, Rebeka niyi niwaju rẹ, mu u, ki o si ma lọ, ki on ki o si ma ṣe aya ọmọ oluwa rẹ, bi OLUWA ti wi.
52. O si ṣe, nigbati iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ọ̀rọ wọn, o wolẹ fun OLUWA.
53. Iranṣẹ na si yọ ohun èlo fadaka, ati èlo wurà jade, ati aṣọ, o si fi wọn fun Rebeka: o si fi ohun iyebiye pẹlu fun arakunrin rẹ̀ ati fun iya rẹ̀.
54. Nwọn si jẹ, nwọn si mu, on ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn si wọ̀ nibẹ̀ li oru ijọ́ na; nwọn si dide li owurọ̀, o si wipe, Ẹ rán mi lọ si ọdọ oluwa mi.
55. Arakunrin ati iya rẹ̀ si wipe, Jẹ ki omidan na ki o ba wa joko ni ijọ́ melokan, bi ijọ́ mẹwa, lẹhin eyini ni ki o ma wa lọ.
56. On si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe da mi duro, OLUWA sa ti ṣe ọ̀na mi ni rere; ẹ rán mi, ki emi ki o le tọ̀ oluwa mi lọ.
57. Nwọn si wipe, Awa o pè omidan na, a o si bère li ẹnu rẹ̀.
58. Nwọn si pè Rebeka, nwọn bi i pe, Iwọ o bá ọkunrin yi lọ? o si wipe, Emi o lọ.
59. Nwọn si rán Rebeka, arabinrin wọn, ati olutọ rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, ati awọn ọkunrin rẹ̀ lọ.
60. Nwọn si súre fun Rebeka, nwọn si wi fun u pe, Iwọ li arabinrin wa, ki iwọ, ki o si ṣe iya ẹgbẹgbẹrun lọnà ẹgbãrun, ki irú-ọmọ rẹ ki o si ni ẹnubode awọn ti o korira wọn.
61. Rebeka si dide, ati awọn omidan rẹ̀, nwọn si gùn awọn ibakasiẹ, nwọn si tẹle ọkunrin na: iranṣẹ na si mu Rebeka, o si ba tirẹ̀ lọ.
62. Isaaki si nti ọ̀na kanga Lahai-roi mbọ̀wá; nitori ilu ìha gusù li on ngbé.
63. Isaaki si jade lọ ṣe àṣaro li oko li aṣalẹ: o si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri i, si kiyesi i, awọn ibakasiẹ mbọ̀wá.