Gẹn 24:41-61 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ninu ibura mi yi, nigbati iwọ ba de ọdọ awọn ibatan mi; bi nwọn kò ba si fi ẹnikan fun ọ, ọrùn rẹ yio si mọ́ kuro ninu ibura mi.

42. Emi si de si ibi kanga loni, mo si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, bi iwọ ba mu ọ̀na àjo mi ti mo nlọ nisisiyi dara:

43. Kiyesi i, mo duro li ẹba kanga omi; ki o si ṣẹ, pe nigbati wundia na ba jade wá ipọn omi, ti mo ba si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi li omi diẹ ki emi mu lati inu ladugbo rẹ;

44. Ti o si wi fun mi pe, Iwọ mu, emi o si pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu: ki on na ki o ṣe obinrin ti OLUWA ti yàn fun ọmọ oluwa mi.

45. Ki emi ki o si tó wi tán li ọkàn mi, kiyesi i, Rebeka jade de ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀; o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o pọn omi: emi si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi mu omi.

46. O si yara, o si sọ ladugbo rẹ̀ kalẹ kuro li ejika rẹ̀, o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu; bẹ̃li emi mu, o si fi fun awọn ibakasiẹ mu pẹlu.

47. Emi si bi i, mo si wipe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? o si wipe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Nahori, ti Milka bí fun u: emi si fi oruka si i ni imu, ati jufù si ọwọ́ rẹ̀.

48. Emi si tẹriba, mo si wolẹ fun OLUWA, mo si fi ibukún fun OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, ti o mu mi tọ̀ ọ̀na titọ lati mu ọmọbinrin arakunrin oluwa mi fun ọmọ rẹ̀ wá.

49. Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin o ba bá oluwa mi lò inu rere ati otitọ, ẹ wi fun mi: bi bẹ̃ si kọ; ẹ wi fun mi: ki emi ki o le pọ̀ si apa ọtún, tabi si òsi.

50. Nigbana ni Labani ati Betueli dahùn nwọn si wipe, Lọdọ OLUWA li ohun na ti jade wá: awa kò le sọ rere tabi buburu fun ọ.

51. Wò o, Rebeka niyi niwaju rẹ, mu u, ki o si ma lọ, ki on ki o si ma ṣe aya ọmọ oluwa rẹ, bi OLUWA ti wi.

52. O si ṣe, nigbati iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ọ̀rọ wọn, o wolẹ fun OLUWA.

53. Iranṣẹ na si yọ ohun èlo fadaka, ati èlo wurà jade, ati aṣọ, o si fi wọn fun Rebeka: o si fi ohun iyebiye pẹlu fun arakunrin rẹ̀ ati fun iya rẹ̀.

54. Nwọn si jẹ, nwọn si mu, on ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn si wọ̀ nibẹ̀ li oru ijọ́ na; nwọn si dide li owurọ̀, o si wipe, Ẹ rán mi lọ si ọdọ oluwa mi.

55. Arakunrin ati iya rẹ̀ si wipe, Jẹ ki omidan na ki o ba wa joko ni ijọ́ melokan, bi ijọ́ mẹwa, lẹhin eyini ni ki o ma wa lọ.

56. On si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe da mi duro, OLUWA sa ti ṣe ọ̀na mi ni rere; ẹ rán mi, ki emi ki o le tọ̀ oluwa mi lọ.

57. Nwọn si wipe, Awa o pè omidan na, a o si bère li ẹnu rẹ̀.

58. Nwọn si pè Rebeka, nwọn bi i pe, Iwọ o bá ọkunrin yi lọ? o si wipe, Emi o lọ.

59. Nwọn si rán Rebeka, arabinrin wọn, ati olutọ rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, ati awọn ọkunrin rẹ̀ lọ.

60. Nwọn si súre fun Rebeka, nwọn si wi fun u pe, Iwọ li arabinrin wa, ki iwọ, ki o si ṣe iya ẹgbẹgbẹrun lọnà ẹgbãrun, ki irú-ọmọ rẹ ki o si ni ẹnubode awọn ti o korira wọn.

61. Rebeka si dide, ati awọn omidan rẹ̀, nwọn si gùn awọn ibakasiẹ, nwọn si tẹle ọkunrin na: iranṣẹ na si mu Rebeka, o si ba tirẹ̀ lọ.

Gẹn 24