Gẹn 23:10-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Efroni si joko lãrin awọn ọmọ Heti: Efroni, ọmọ Heti, si dá Abrahamu lohùn li eti gbogbo awọn ọmọ Heti, ani li eti gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀ wipe,

11. Bẹ̃kọ, Oluwa mi, gbọ́ ti emi, mo fi oko na fun ọ, ati ihò ti o wà nibẹ̀, mo fi fun ọ: li oju awọn ọmọ awọn enia mi ni mo fi i fun ọ: sin okú rẹ.

12. Abrahamu si tẹriba niwaju awọn enia ilẹ na.

13. O si wi fun Efroni, li eti awọn enia ilẹ na pe, Njẹ bi iwọ o ba fi i fun mi, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ti emi: emi o san owo oko na fun ọ; gbà a lọwọ mi, emi o si sin okú mi nibẹ̀.

14. Efroni si da Abrahamu li ohùn, o wi fun u pe,

15. Oluwa mi, gbọ́ ti emi: irinwo òṣuwọn ṣekeli fadaka ni ilẹ jẹ; kili eyini lãrin temi tirẹ? sa sin okú rẹ.

16. Abrahamu si gbọ́ ti Efroni; Abrahamu si wọ̀n iye fadaka na fun Efroni, ti o sọ li eti awọn ọmọ Heti, irinwo òṣuwọn ṣekeli fadaka, ti o kọja lọdọ awọn oniṣòwo.

17. Oko Efroni ti o wà ni Makpela, ti o wà niwaju Mamre, oko na, ati ihò ti o wà ninu rẹ̀, ati gbogbo igi ti o wà ni oko na, ti o wà ni gbogbo ẹba rẹ̀ yika, li a ṣe daju,

18. Fun Abrahamu ni ilẹ-ini, li oju awọn ọmọ Heti, li oju gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀.

19. Lẹhin eyi li Abrahamu sin Sara, aya rẹ̀, ninu ihò oko Makpela, niwaju Mamre: eyi nã ni Hebroni ni ilẹ Kenaani.

Gẹn 23