O si wi fun Efroni, li eti awọn enia ilẹ na pe, Njẹ bi iwọ o ba fi i fun mi, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ti emi: emi o san owo oko na fun ọ; gbà a lọwọ mi, emi o si sin okú mi nibẹ̀.