12. O si wipe, Máṣe fọwọkàn ọmọde nì, bẹ̃ni iwọ kó gbọdọ ṣe e ni nkan: nitori nisisiyi emi mọ̀ pe iwọ bẹ̀ru Ọlọrun, nigbati iwọ kò ti dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo.
13. Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, lẹhin rẹ̀, àgbo kan ti o fi iwo rẹ̀ há ni pantiri: Abrahamu si lọ o mu àgbo na, o si fi i rubọ sisun ni ipò ọmọ rẹ̀.
14. Abrahamu si pè orukọ ibẹ̀ na ni Jehofajire: bi a ti nwi titi di oni yi, Li oke OLUWA li a o gbé ri i.
15. Angeli OLUWA nì si kọ si Abrahamu lati ọrun wá lẹrinkeji,
16. O si wipe, Emi tikalami ni mo fi bura, li OLUWA wi, nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo:
17. Pe ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bíbisi emi o mu irú-ọmọ rẹ bísi i bi irawọ oju-ọrun, ati bi iyanrin eti okun; irú-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn;
18. Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ ti gbà ohùn mi gbọ́.
19. Abrahamu si pada tọ̀ awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, nwọn si dide, nwọn si jùmọ lọ si Beer-ṣeba; Abrahamu si joko ni Beer-ṣeba.
20. O si ṣe, lẹhin nkan wọnyi, li a sọ fun Abrahamu pe, kiyesi i, Milka, on pẹlu si ti bimọ fun Nahori, arakunrin rẹ;
21. Husi akọ́bi rẹ̀, ati Busi arakunrin rẹ̀, ati Kemueli baba Aramu.
22. Ati Kesedi, ati Haso, ati Pildaṣi, ati Jidlafu, ati Betueli.
23. Betueli si bí Rebeka: awọn mẹjọ yi ni Milka bí fun Nahori, arakunrin Abrahamu.
24. Ati àle rẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ Rehuma, on pẹlu si bí Teba, ati Gahamu, ati Tahaṣi, ati Maaka.