11. Orukọ ekini ni Pisoni: on li eyiti o yi gbogbo ilẹ Hafila ká, nibiti wurà wà;
12. Wurà ilẹ na si dara: nibẹ ni bedeliumu (ojia) wà ati okuta oniki.
13. Orukọ odò keji si ni Gihoni: on na li eyiti o yi gbogbo ilẹ Kuṣi ká.
14. Ati orukọ odò kẹta ni Hiddekeli: on li eyiti nṣàn lọ si ìha ìla-õrùn Assiria. Ati odò kẹrin ni Euferate.
15. OLUWA Ọlọrun si mu ọkunrin na, o si fi i sinu ọgbà Edeni lati ma ro o, ati lati ma ṣọ́ ọ.
16. OLUWA Ọlọrun si fi aṣẹ fun ọkunrin na pe, Ninu gbogbo igi ọgbà ni ki iwọ ki o ma jẹ:
17. Ṣugbọn ninu igi ìmọ rere ati bururu nì, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀: nitoripe li ọjọ́ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀ kikú ni iwọ o kú.
18. OLUWA Ọlọrun si wipe, kò dara ki ọkunrin na ki o nikan ma gbé; emi o ṣe oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u.
19. Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun si ti dá ẹranko igbẹ gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun gbogbo; o si mu wọn tọ̀ Adamu wá lati wò orukọ ti yio sọ wọn; orukọkorukọ ti Adamu si sọ olukuluku ẹda alãye, on li orukọ rẹ̀.
20. Adamu si sọ ẹran-ọ̀sin gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko igbẹ gbogbo, li orukọ; ṣugbọn fun Adamu a kò ri oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u.
21. OLUWA Ọlọrun si mu orun ìjika kùn Adamu, o si sùn: o si yọ ọkan ninu egungun-ìha rẹ̀, o si fi ẹran di ipò rẹ̀:
22. OLUWA Ọlọrun si fi egungun-ìha ti o mu ni ìha ọkunrin na mọ obinrin, o si mu u tọ̀ ọkunrin na wá.
23. Adamu si wipe, Eyiyi li egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ara ninu ẹran-ara mi: Obinrin li a o ma pè e, nitori ti a mu u jade lati ara ọkunrin wá.
24. Nitori na li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on iya rẹ̀ silẹ, yio si fi ara mọ́ aya rẹ̀: nwọn o si di ara kan.
25. Awọn mejeji si wà ni ìhoho, ati ọkunrin na ati obinrin rẹ̀, nwọn kò si tiju.