Gẹn 19:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN Angeli meji si wá si Sodomu li aṣalẹ; Loti si joko li ẹnu-bode Sodomu: bi Loti si ti ri wọn, o dide lati pade wọn: o si dojubolẹ;

2. O si wipe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnyin oluwa mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ yà si ile ọmọ-ọdọ nyin, ki ẹ si wọ̀, ki ẹ si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ẹnyin o si dide ni kùtukutu, ki ẹ si ma ba ti nyin lọ. Nwọn si wipe, Ndao; ṣugbọn awa o joko ni igboro li oru oni.

3. O si rọ̀ wọn gidigidi; nwọn si yà tọ̀ ọ, nwọn si wọ̀ inu ile rẹ̀; o si sè àse fun wọn, o si dín àkara alaiwu fun wọn, nwọn si jẹ.

4. Ṣugbọn ki nwọn ki o to dubulẹ, awọn ọkunrin ara ilu na, awọn ọkunrin Sodomu, nwọn yi ile na ká, ati àgba ati ewe, gbogbo enia lati ori igun mẹrẹrin wá.

5. Nwọn si pè Loti, nwọn si bi i pe, Nibo li awọn ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá li alẹ yi wà? mu wọn jade fun wa wá, ki awa ki o le mọ̀ wọn.

6. Loti si jade tọ̀ wọn lọ li ẹnu-ọ̀na, o si sé ilẹkun lẹhin rẹ̀.

7. O si wipe, Arakunrin, emi bẹ̀ nyin, ẹ máṣe hùwa buburu bẹ̃.

8. Kiyesi i nisisiyi, emi li ọmọbinrin meji ti kò ti imọ̀ ọkunrin: emi bẹ̀ nyin, ẹ jẹ ki nmu wọn jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o si fi wọn ṣe bi o ti tọ́ loju nyin: ṣugbọn awọn ọkunrin wọnyi ṣa ni ki ẹ má ṣe ni nkan; nitorina ni nwọn sa ṣe wá si abẹ orule mi.

9. Nwọn si wipe, Bì sẹhin. Nwọn si tun wipe, Eyiyi wá iṣe atipo, on si fẹ iṣe onidajọ: njẹ iwọ li a o tilẹ ṣe ni buburu jù wọn lọ. Nwọn si rọlù ọkunrin na, ani Loti, nwọn si sunmọ ọ lati fọ́ ilẹkun.

10. Ṣugbọn awọn ọkunrin na nà ọwọ́ wọn, nwọn si fà Loti mọ́ ọdọ sinu ile, nwọn si tì ilẹkun.

11. Nwọn si bù ifọju lù awọn ọkunrin ti o wà li ẹnu-ọ̀na ile na, ati ewe ati àgba: bẹ̃ni nwọn dá ara wọn li agara lati ri ẹnu-ọ̀na.

Gẹn 19