Nwọn si wipe, Bì sẹhin. Nwọn si tun wipe, Eyiyi wá iṣe atipo, on si fẹ iṣe onidajọ: njẹ iwọ li a o tilẹ ṣe ni buburu jù wọn lọ. Nwọn si rọlù ọkunrin na, ani Loti, nwọn si sunmọ ọ lati fọ́ ilẹkun.