Gẹn 18:3-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. O si wipe, OLUWA mi, njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, emi bẹ̀ ọ, máṣe kọja lọ kuro lọdọ ọmọ-ọdọ rẹ:

4. Jẹ ki a mu omi diẹ wá nisisiyi, ki ẹnyin ki o si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ki ẹnyin ki o si simi labẹ igi:

5. Emi o si mu onjẹ diẹ wá, ki ẹnyin si fi ọkàn nyin balẹ; lẹhin eyini ki ẹnyin ma kọja lọ: njẹ nitorina li ẹnyin ṣe tọ̀ ọmọ-ọdọ nyin wá. Nwọn si wipe, Ṣe bẹ̃ bi iwọ ti wi.

6. Abrahamu si yara tọ̀ Sara lọ ninu agọ́, o wipe, Yara mu òṣuwọn iyẹfun daradara mẹta, ki o pò o, ki o si dín akara.

7. Abrahamu si sure lọ sinu agbo, o si mu ẹgbọrọ-malu kan ti o rọ̀ ti o dara, o fi fun ọmọkunrin kan; on si yara lati sè e.

8. O si mu orí-amọ́, ati wàra, ati ẹgbọrọ malu ti o sè, o si gbé e kalẹ niwaju wọn: on si duro tì wọn li abẹ igi na, nwọn si jẹ ẹ.

9. Nwọn si bi i pe, nibo ni Sara aya rẹ wà? o si wipe, wò o ninu agọ́.

10. O si wipe, Emi o si tun pada tọ̀ ọ wá nitõtọ ni iwoyi amọ́dun; si kiyesi i, Sara aya rẹ yio li ọmọkunrin kan. Sara si gbọ́ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ti o wà lẹhin ọkunrin na.

11. Njẹ Abrahamu on Sara gbó, nwọn si pọ̀ li ọjọ́; o si dẹkun ati ma ri fun Sara bi ìwa obinrin.

12. Nitorina Sara rẹrin ninu ara rẹ̀ wipe, Lẹhin igbati mo di ogbologbo tan, emi o ha li ayọ̀, ti oluwa mi si di ogbologbo pẹlu?

13. OLUWA si wi fun Abrahamu pe, Nitori kini Sara ṣe nrẹrin wipe, Emi o ha bímọ nitõtọ, ẹniti o ti gbó tán?

14. Ohun kan ha ṣoro fun OLUWA? li akoko ti a dá emi o pada tọ̀ ọ wa, ni iwoyi amọ́dun, Sara yio si li ọmọkunrin kan.

Gẹn 18