2. O si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, ọkunrin mẹta duro li ẹba ọdọ rẹ̀: nigbati o si ri wọn, o sure lati ẹnu-ọ̀na agọ́ lọ ipade wọn, o si tẹriba silẹ.
3. O si wipe, OLUWA mi, njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, emi bẹ̀ ọ, máṣe kọja lọ kuro lọdọ ọmọ-ọdọ rẹ:
4. Jẹ ki a mu omi diẹ wá nisisiyi, ki ẹnyin ki o si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ki ẹnyin ki o si simi labẹ igi:
5. Emi o si mu onjẹ diẹ wá, ki ẹnyin si fi ọkàn nyin balẹ; lẹhin eyini ki ẹnyin ma kọja lọ: njẹ nitorina li ẹnyin ṣe tọ̀ ọmọ-ọdọ nyin wá. Nwọn si wipe, Ṣe bẹ̃ bi iwọ ti wi.
6. Abrahamu si yara tọ̀ Sara lọ ninu agọ́, o wipe, Yara mu òṣuwọn iyẹfun daradara mẹta, ki o pò o, ki o si dín akara.
7. Abrahamu si sure lọ sinu agbo, o si mu ẹgbọrọ-malu kan ti o rọ̀ ti o dara, o fi fun ọmọkunrin kan; on si yara lati sè e.
8. O si mu orí-amọ́, ati wàra, ati ẹgbọrọ malu ti o sè, o si gbé e kalẹ niwaju wọn: on si duro tì wọn li abẹ igi na, nwọn si jẹ ẹ.
9. Nwọn si bi i pe, nibo ni Sara aya rẹ wà? o si wipe, wò o ninu agọ́.
10. O si wipe, Emi o si tun pada tọ̀ ọ wá nitõtọ ni iwoyi amọ́dun; si kiyesi i, Sara aya rẹ yio li ọmọkunrin kan. Sara si gbọ́ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ti o wà lẹhin ọkunrin na.
11. Njẹ Abrahamu on Sara gbó, nwọn si pọ̀ li ọjọ́; o si dẹkun ati ma ri fun Sara bi ìwa obinrin.
12. Nitorina Sara rẹrin ninu ara rẹ̀ wipe, Lẹhin igbati mo di ogbologbo tan, emi o ha li ayọ̀, ti oluwa mi si di ogbologbo pẹlu?
13. OLUWA si wi fun Abrahamu pe, Nitori kini Sara ṣe nrẹrin wipe, Emi o ha bímọ nitõtọ, ẹniti o ti gbó tán?
14. Ohun kan ha ṣoro fun OLUWA? li akoko ti a dá emi o pada tọ̀ ọ wa, ni iwoyi amọ́dun, Sara yio si li ọmọkunrin kan.
15. Sara si sẹ, wipe, Emi kò rẹrin; nitoriti o bẹ̀ru. On si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn iwọ rẹrin.