Gẹn 18:14-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ohun kan ha ṣoro fun OLUWA? li akoko ti a dá emi o pada tọ̀ ọ wa, ni iwoyi amọ́dun, Sara yio si li ọmọkunrin kan.

15. Sara si sẹ, wipe, Emi kò rẹrin; nitoriti o bẹ̀ru. On si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn iwọ rẹrin.

16. Awọn ọkunrin na si dide kuro nibẹ̀, nwọn kọju sihà Sodomu: Abrahamu si ba wọn lọ lati sìn wọn de ọ̀na.

17. OLUWA si wipe, Emi o ha pa ohun ti emi o ṣe mọ́ fun Abrahamu:

18. Nitori pe, Abrahamu yio sa di orilẹ-ède nla ati alagbara, ati gbogbo orilẹ-ède aiye li a o bukun fun nipasẹ rẹ̀?

19. Nitoriti mo mọ̀ ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati fun awọn ara ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọ̀na OLUWA mọ́ lati ṣe ododo ati idajọ; ki OLUWA ki o le mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun u.

20. OLUWA si wipe, Nitori ti igbe Sodomu on Gomorra pọ̀, ati nitori ti ẹ̀ṣẹ wọn pàpọju.

21. Emi o sọkalẹ lọ nisisiyi, ki nri bi nwọn tilẹ ṣe, gẹgẹ bi okikí igbe rẹ̀, ti o de ọdọ mi; bi bẹ si kọ, emi o mọ̀.

22. Awọn ọkunrin na si yi oju wọn pada kuro nibẹ̀, nwọn si lọ si Sodomu: ṣugbọn Abrahamu duro sibẹ̀ niwaju OLUWA.

23. Abrahamu si sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Iwọ o ha run olododo pẹlu enia buburu?

24. Bọya ãdọta olododo yio wà ninu ilu na: iwọ o ha run u, iwọ ki yio ha dá ibẹ̀ na si nitori ãdọta olododo ti o wà ninu rẹ̀?

25. O ha dára, ti iwọ o fi ṣe bi irú eyi, lati run olododo pẹlu enia buburu; ti awọn olododo yio fi dabi awọn enia buburu, o ha dára: Onidajọ gbogbo aiye ki yio ha ṣe eyi ti o tọ́?

26. OLUWA si wipe, Bi mo ba ri ãdọta olododo ninu ilu Sodomu, njẹ emi o dá gbogbo ibẹ̀ si nitori wọn.

27. Abrahamu si dahùn o si wipe, Wò o nisisiyi, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ, emi ẹniti iṣe erupẹ ati ẽru.

28. Bọya marun a dín ninu ãdọta olododo na: iwọ o ha run gbogbo ilu na nitori marun? On si wipe, Bi mo ba ri marunlelogoji nibẹ̀, emi ki yio run u.

29. O si tun sọ fun u ẹ̀wẹ, o ni, Bọya, a o ri ogoji nibẹ̀, On si wipe, Emi ki o run u nitori ogoji.

Gẹn 18