Gẹn 16:5-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Sarai si wi fun Abramu pe, Ẹbi mi wà lori rẹ: emi li o fi ọmọbinrin ọdọ mi fun ọ li àiya; nigbati o si ri pe on loyun, mo di ẹ̀gan li oju rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe idajọ lãrin temi tirẹ.

6. Ṣugbọn Abramu wi fun Sarai pe, Wò o, ọmọbinrin ọdọ rẹ wà li ọwọ́ rẹ: fi i ṣe bi o ti tọ́ li oju rẹ. Nigbati Sarai nfõró rẹ̀, o sá lọ kuro lọdọ rẹ̀.

7. Angeli OLUWA si ri i li ẹba isun omi ni ijù, li ẹba isun omi li ọ̀na Ṣuri.

8. O si wipe, Hagari ọmọbinrin ọdọ Sarai, nibo ni iwọ ti mbọ̀? nibo ni iwọ si nrè? O si wipe, emi sá kuro niwaju Sarai oluwa mi.

9. Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Pada, lọ si ọdọ oluwa rẹ, ki o si tẹriba fun u.

10. Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Ni bíbi emi o mu iru-ọmọ rẹ bísi i, a ki yio si le kà wọn fun ọ̀pọlọpọ.

11. Angeli OLUWA na si wi fun u pe, kiyesi i iwọ loyun, iwọ o si bí ọmọkunrin, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Iṣmaeli; nitoriti OLUWA ti gbọ́ ohùn arò rẹ.

12. Jagidijagan enia ni yio si ṣe; ọwọ́ rẹ̀ yio wà lara enia gbogbo, ọwọ́ enia gbogbo yio si wà lara rẹ̀: on o si ma gbé iwaju gbogbo awọn arakunrin rẹ̀.

13. O si pè orukọ OLUWA ti o ba a sọ̀rọ ni, Iwọ Ọlọrun ti o ri mi: nitori ti o wipe, Emi ha wá ẹniti o ri mi kiri nihin?

14. Nitori na li a ṣe npè kanga na ni Beer-lahai-roi: kiyesi i, o wà li agbedemeji Kadeṣi on Beredi.

15. Hagari si bí ọmọkunrin kan fun Abramu: Abramu si pè orukọ ọmọ ti Hagari bí ni Iṣmaeli.

Gẹn 16