Gẹn 14:6-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ati awọn ara Hori li oke Seiri wọn, titi o fi de igbo Parani, ti o wà niha ijù.

7. Nwọn si pada, nwọn si wá si Enmiṣpati, eyini ni Kadeṣi, nwọn si kọlu gbogbo oko awọn ara Amaleki, ati awọn ara Amori ti o tẹdo ni Hasesontamari pẹlu.

8. Ọba Sodomu si jade, ati ọba Gomorra, ati ọba Adma, ati ọba Seboimu, ati ọba Bela, (eyini ni Soari;) nwọn si tẹgun si ara wọn li afonifoji Siddimu;

9. Si Kedorlaomeri ọba Elamu, ati si Tidali ọba awọn orilẹ-ède, ati Amrafeli ọba Ṣinari, ati Arioku ọba Ellasari, ọba mẹrin si marun.

10. Afonifoji Siddimu si jẹ kìki kòto ọ̀da-ilẹ; awọn ọba Sodomu ati ti Gomorra sá, nwọn si ṣubu nibẹ̀; awọn ti o si kù sálọ si ori oke.

Gẹn 14