1. O SI ṣe li ọjọ́ Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu, ati Tidali ọba awọn orilẹ-ède;
2. Ti nwọn ba Bera ọba Sodomu jagun, pẹlu Birṣa ọba Gomorra, Ṣinabu ọba Adma, ati Semeberi ọba Seboimu, pẹlu ọba Bela (eyini ni Soari).
3. Gbogbo awọn wọnyi li o dapọ̀ li afonifoji Siddimu, ti iṣe Okun Iyọ̀.
4. Nwọn sìn Kedorlaomeri li ọdún mejila, li ọdún kẹtala nwọn ṣọ̀tẹ.
5. Li ọdún kẹrinla ni Kedorlaomeri, wá ati awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn kọlu awọn Refaimu ni Aṣteroti-Karnaimu, ati awọn Susimu ni Hamu, ati awọn Emimu ni pẹtẹlẹ Kiriataimu,
6. Ati awọn ara Hori li oke Seiri wọn, titi o fi de igbo Parani, ti o wà niha ijù.
7. Nwọn si pada, nwọn si wá si Enmiṣpati, eyini ni Kadeṣi, nwọn si kọlu gbogbo oko awọn ara Amaleki, ati awọn ara Amori ti o tẹdo ni Hasesontamari pẹlu.