Li ọdún kẹrinla ni Kedorlaomeri, wá ati awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn kọlu awọn Refaimu ni Aṣteroti-Karnaimu, ati awọn Susimu ni Hamu, ati awọn Emimu ni pẹtẹlẹ Kiriataimu,