6. Ilẹ na kò si le igbà wọn, ki nwọn ki o le igbé pọ̀: nitori ini wọn pọ̀, bẹ̃nì nwọn kò si le gbé pọ̀.
7. Bẹ̃ni gbolohùn asọ̀ si wà lãrin awọn darandaran Abramu, ati awọn darandaran Loti: ati awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi ngbé ilẹ na ni ìgba na.
8. Abramu si wi fun Loti pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki gbolohùn asọ̀ ki o wà lãrin temi tirẹ, ati lãrin awọn darandaran mi, ati awọn darandaran rẹ; nitori pe ará li awa iṣe.
9. Gbogbo ilẹ kọ́ eyi niwaju rẹ? emi bẹ̀ ọ, yà ara rẹ kuro lọdọ mi: bi iwọ ba pọ̀ si apa òsi, njẹ emi o pọ̀ si ọtún; tabi bi iwọ ba pọ̀ si apa ọtùn, njẹ emi o pọ̀ si òsi.
10. Loti si gboju rẹ̀ si oke, o si wò gbogbo àgbegbe Jordani, pe o li omi nibi gbogbo, ki OLUWA ki o to pa Sodomu on Gomorra run, bi ọgbà OLUWA, bi ilẹ Egipti, bi iwọ ti mbọ̀wa si Soari.
11. Nigbana ni Loti yàn gbogbo àgbegbe Jordani fun ara rẹ̀; Loti si nrìn lọ si ìha ìla-õrùn: bẹ̃ni nwọn yà ara wọn, ekini kuro lọdọ ekeji.
12. Abramu si joko ni ilẹ Kenaani, Loti si joko ni ilu àgbegbe nì, o si pagọ́ rẹ̀ titi de Sodomu.