Gẹn 11:7-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a sọkalẹ lọ, ki a dà wọn li ède rú nibẹ̀, ki nwọn ki o máṣe gbedè ara wọn mọ́.

8. Bẹ̃li OLUWA tú wọn ká lati ibẹ̀ lọ si ori ilẹ gbogbo: nwọn si ṣíwọ ilu ti nwọn ntẹdó.

9. Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Babeli; nitori ibẹ̀ li OLUWA gbe dà ède araiye rú, lati ibẹ̀ lọ OLUWA si tú wọn ká kiri si ori ilẹ gbogbo.

10. Wọnyi ni iran Ṣemu: Ṣemu jẹ ẹni ọgọrun ọdún, o si bí Arfaksadi li ọdún keji lẹhin kíkun-omi.

11. Ṣemu si wà li ẹ̃dẹgbẹta ọdún, lẹhin igbati o bí Arfaksadi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

12. Arfaksadi si wà li arundilogoji ọdún, o si bí Ṣela:

13. Arfaksadi si wà ni irinwo ọdún o le mẹta, lẹhin igbati o bí Ṣela tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

Gẹn 11