11. Nitorina Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà; Nitõtọ, nitori ti iwọ ti sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́ nipa ohun ẹgbin rẹ, ati pẹlu gbogbo ohun irira rẹ, nitori na li emi o ṣe dín ọ kù, oju mi kì yio dasi, bẹ̃ni emi kì yio ṣãnu fun ọ.
12. Idámẹta rẹ yio kú nipa ajakalẹ arùn, nwọn o si run li ãrin rẹ nipa iyàn, idámẹta yio si ṣubu nipa idà yi ọ ka kiri, emi o si tú idamẹta ká si gbogbo ẹfũfù, emi o si yọ idà tẹle wọn.
13. Bayi ni ibinu mi o ṣẹ, emi o si mu ibinu mi duro lori wọn, inu mi yio si tutù: nwọn o si mọ̀ pe emi Oluwa ti sọ ọ ninu itara mi, nigbati mo ba pari ibinu mi ninu wọn.
14. Emi o si fi ọ ṣòfo, emi o si sọ ọ di ẹ̀gan lãrin awọn orilẹ-ède ti o yi ọ ka kiri, li oju gbogbo awọn ti nkọja.
15. Bẹ̃ni yio si di ẹ̀gan ati ẹsín, ẹkọ́ ati iyanu si awọn orilẹ-ède ti o wà yi ọ ka kiri; nigbati emi o ṣe idajọ ninu rẹ ninu ibinu, ati ninu irunu on ibawi irunu. Emi Oluwa li o sọ ọ.
16. Nigbati emi o rán ọfà buburu iyàn si wọn, eyi ti yio jẹ fun iparun wọn, eyi ti emi o rán lati run nyin: emi o si sọ iyàn di pupọ̀ fun nyin, emi o si ṣẹ́ ọpá onjẹ nyin.
17. Bẹ̃ni emi o rán iyàn ati ẹranko buburu si nyin, nwọn o si gbà ọ li ọmọ, ajàkalẹ arùn ati ẹjẹ̀ yio si kọja lãrin rẹ, emi o si mu idà wá sori rẹ. Emi Oluwa li o ti sọ ọ.