Esek 25:13-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi pẹlu yio nawọ mi si Edomu, emi o si ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀; emi o si sọ ọ di ahoro lati Temani; ati awọn ti Dedani, yio ti ipa idà ṣubu.

14. Emi o si gbe ẹ̀san mi le ori Edomu lati ọwọ́ Israeli enia mi: nwọn o si ṣe ni Edomu gẹgẹ bi ibinu mi, ati gẹgẹ bi irúnu mi; nwọn o si mọ̀ ẹ̀san mi, li Oluwa Ọlọrun wi.

15. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti awọn ara Filistia ti lò ilo ẹsan, ti nwọn si ti fi ọkàn ti o kún fun arankàn gbẹsan, lati pa a run, nitori irira atijọ.

16. Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o nà ọwọ́ mi le awọn ara Filistia, emi o si ke awọn ara Keriti kuro, emi o si run awọn iyokù ti eti okun.

17. Emi o si san ẹsan nla lara wọn nipa ibáwi gbigbona; nwọn o si mọ̀ pe, emi li Oluwa, nigbati emi o gbe ẹsan mi le wọn.

Esek 25