Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi pẹlu yio nawọ mi si Edomu, emi o si ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀; emi o si sọ ọ di ahoro lati Temani; ati awọn ti Dedani, yio ti ipa idà ṣubu.