Eks 5:11-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Ẹ lọ, ẹ wá koriko nibiti ẹnyin gbé le ri i: ṣugbọn a ki yio ṣẹ nkan kù ninu iṣẹ nyin.

12. Bẹ̃li awọn enia na si tuka kiri ká gbogbo ilẹ Egipti lati ma ṣà idi koriko ni ipò koriko.

13. Awọn akoniṣiṣẹ lé wọn ni ire wipe, Ẹ ṣe iṣẹ nyin pé, iṣẹ ojojumọ́ nyin, bi igbati koriko mbẹ.

14. Ati awọn olori awọn ọmọ Israeli, ti awọn akoniṣiṣẹ Farao yàn lé wọn, li a nlù, ti a si mbilère pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò ṣe iṣẹ nyin pé ni briki ṣiṣe li ana ati li oni, bi ìgba atẹhinwá?

15. Nigbana li awọn olori awọn ọmọ Israeli wá, nwọn si ke tọ̀ Farao wipe, Ẽṣe ti iwọ fi nṣe awọn iranṣẹ rẹ bayi?

16. A kò fi koriko fun awọn iranṣẹ rẹ, nwọn si nwi fun wa pe, Ẹ ṣe briki: si kiyesi i, a nlù awọn iranṣẹ rẹ; ṣugbọn lọwọ awọn enia rẹ li ẹbi wà.

17. Ṣugbọn on wipe, Ẹnyin ọlẹ, ẹnyin ọlẹ: nitorina li ẹ ṣe wipe, Jẹ ki a lọ ṣẹbọ si OLUWA.

18. Njẹ ẹ lọ nisisiyi, ẹ ṣiṣẹ; a ki yio sá fi koriko fun nyin, sibẹ̀ iye briki nyin yio pé.

19. Awọn olori awọn ọmọ Israeli si ri pe, ọ̀ran wọn kò li oju, lẹhin igbati a wipe, Ẹ ki o dinkù ninu iye briki nyin ojojumọ́.

20. Nwọn si bá Mose on Aaroni, ẹniti o duro lati pade wọn bi nwọn ti nti ọdọ Farao jade wá:

21. Nwọn si wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o wò nyin, ki o si ṣe idajọ; nitoriti ẹnyin mu wa di okú-õrùn li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀, lati fi idá lé wọn lọwọ lati pa wa.

22. Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wi fun u pe, OLUWA, ẽtiṣe ti o fi ṣe buburu si awọn enia yi bẹ̃? ẽtiṣe ti o fi rán mi?

23. Nitori igbati mo ti tọ̀ Farao wá lati sọ̀rọ li orukọ rẹ, buburu li o ti nṣe si awọn enia yi; bẹ̃ni ni gbigbà iwọ kò si gbà awọn enia rẹ.

Eks 5