Eks 35:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MOSE si pè apejọ gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Wọnyi li ọ̀rọ ti OLUWA palaṣẹ pe, ki ẹnyin ki o ṣe wọn.

2. Ijọ́ mẹfa ni ki a fi ṣe iṣẹ, ṣugbọn ijọ́ keje ni yio ṣe ọjọ́ mimọ́ fun nyin, ọjọ́ isimi ọ̀wọ si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹ ninu rẹ̀ li a o lupa nitõtọ.

3. Ẹnyin kò gbọdọ da iná ni ile nyin gbogbo li ọjọ́ isimi.

Eks 35